Ọmọ ibilẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yoruba People, I.Y.P) ti orílẹ̀ èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yorùbá, D.R.Y), gẹ́gẹ́ bí a ti ṣe mọ̀ wípé, àlàkalẹ̀ tí Olódùmarè fún wa nípasẹ̀ Màmá wa, Ìyá-Ààfin Modúpẹ́ Onítirí-Abíọ́lá, jẹ́ èyí tí ohun gbogbo yóò gba àyípadà ọ̀tun, bẹ̀rẹ̀ láti ìwa wa, ìgbésí ayé wa lápapọ̀, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.
Gẹ́gẹ́ bí màmá wá Ìyá ààfin Modupẹọla Onitiri-Abiọla, tí Olódùmarè lò fún òmìnira àwa ìran Yorùbá ṣe máa ń sọ fún wa wípé, àlàkalẹ̀ ètò ìṣàkóso tí Olódùmarè fi rán àwọn sí àwa ọmọ Yorùbà yóò dá wa padà sí orísun wa.
Màmá sọ fún wa nípa ètò ìwòsàn wípé, a máa ṣe ìgbélárugẹ ìlànà àwọn babańlá wa láti ṣe ìtọ́jú ìwòsàn.
Èdè Yorùbá ni a ó máa sọ ní ilé-ẹ̀kọ́, ní ilé-iṣẹ́ àti fún gbogbo àkọsílẹ̀-àdéhùn ní Ilẹ̀ Yorùbá, àwọn oúnjẹ wa ní ilé-olónjẹ ni a ó máà ṣe gẹ́gẹ́bí tí ìṣẹ̀dálè, a óò padà sí ìwà ọmọlúwàbí wa bakanna, nítorí pé orílẹ̀ èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá kò ní fi àyè gbà ìwà tí kò tọ́, bẹ́ẹ̀ sì ni ìṣẹ́ àti ìyà yóò dópin ní orílẹ̀ èdè wa.
Ìbùkún ni fún Orílẹ̀ Èdè mi, Orílẹ̀ Èdè Olómìnira Tiwantiwa Ti Yorùbá, D.R.Y