Ṣèyí Makinde aláìmọ èyí tó kàn ṣáà ń dá ọ̀ràn kún ọ̀ràn, bẹ́ẹ̀ ló ṣì ń tan àwọn ará ìlú pé òun sì ni gómìnà Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, ṣé ajá tí yóò sọnù kìí gbọ́ fèrè ọdẹ.
Ìròyìn tó tún tẹ̀ wá lọ́wọ́ ni pé, Seyi Makinde fún àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba kan ní ìgbéga lẹ́nu iṣẹ́, ó sì gba àwọn kan tí wọ́n ti dá dúró lẹ́nu iṣẹ́ padà, àkójọpọ̀ gbogbo wọn sì jẹ́ ẹgbẹ̀sán.
A fẹ́ jẹ́ kí gbogbo ẹ̀yin ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yorùbá People I.Y.P) tí ọ̀rọ̀ yí ò bá tíì yé dáadáa mọ̀ wípé, Seyi Makinde àti àwọn yòókù rẹ̀ tí wọ́n ń jẹ gàba lórí ilẹ̀ wa ń dá ọ̀ràn mọ́ ọ̀ràn ni, wọn ò ní ẹ̀tọ́ kankan lábẹ́ òfin àjọ àgbáyé láti wà ní orí ilẹ̀ tó jẹ́ ti orílẹ̀ èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yorùbá, D.R.Y) títí di àkókò yí.
Lẹ́yìn tí a ti kéde òmìnira wa ní ogúnjọ́ oṣù Bélú ẹgbàáọdúnóléméjìlélógún tí a sì tún ṣe ìbúra wọlé fún olórí adelé wá bàbá wa Mobọlaji Ọlawale Akinọla Ọmọkọrẹ ní ọjọ́ Kejìlá oṣù Igbe ẹgbàáọdúnólémẹ́rìnlélógún.
Àwọn ará ìlú tí ọ̀rọ̀ yí kàn kọ́ ló bí wa nínú bíkòṣe Seyi Makinde tó jẹ́ gàba lórí ilẹ̀ D.R.Y, lẹ́yìn tó ti b’ọwọ́lù ìwé tí àwa ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá kọ síi wípé a fẹ́ gba àwọn ohun tó jẹ́ ti wa padà. Ìwé tí o bu’wọ́lù yí túmọ̀ sí pé, o faramọ, àti pé o ṣetán láti kúrò lórí àga orílẹ̀ èdè D.R.Y tí o jókòó sí.
Ẹ kọjá sí ìlú aríremáṣe nàìjíríà yín, níbẹ̀ ni ẹ ti leè máa pa àṣẹ, ọ̀rọ̀ yí ò rújú rárá bẹ́ẹ̀ sì ni kò fa ariwo. Ẹ ò rí ibi sá sí, abẹ́rẹ́ ti bọ́ lọ́wọ́ adẹ́tẹ̀ yín, ó d’ète. Ìgbà díẹ̀ ló kù, tí àwọn adelé wa máa wọlé sí oríkò ilé iṣẹ́ ìjọba wa, ojú yín yóò ríi láìpẹ́ yí, àbámọ̀ yóò sì gbẹ̀yìn gbogbo yín.