Ohun tí ó jẹ́ ètò-àtọwọ́dá ọmọ-ènìyàn; ètò àtọwọ́dá àwọn òyìnbó-amunisìn, njẹ́ ètò-àtọwọ́dá ọmọ-ènìyàn yí, ní Ẹ̀tọ́ kankan, níbikíbi ní àgbáyé láti jẹgàba sórí ohun tí Olódùmarè gbé kalẹ̀ nípa ìṣẹ̀dá ọwọ́ rẹ̀?

Ẹ jẹ́ kí á tún gbé-e kalẹ̀ ní ọ̀nà míràn. Ṣé ní àìpẹ́ yí ni Màmá Ìran Yorùbá, Ìyá-Ààfin Modúpẹ́ Onítirí-Abíọ́lá, gbe síta pé Ètò àwọn ÒYÌNBÓ-AKÓNILẸ́RÚ, àwọn Amúnisìn, ni Nàìjíríà jẹ́, àti pé kìí ṣe Orílẹ̀-Èdè Rárá, ṣùgbọ́n tí Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá Democratic Republic of the Yoruba, D.R.Y) jẹ́ Orílẹ̀-Èdè, gẹ́gẹ́bí Ìtumọ̀ oun tí àgbáyé mọ̀ sí Orílẹ̀-Èdè – èyí tí ó jẹ́ ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ ọmọ-ènìyàn tí wọ́n ní Orísun kan-náà, nípasẹ̀ èyí tí wọ́n fi jẹ́ Ìràn kan-náà, èyí tí kò tilẹ̀ tún wá ní Àbùlà ní ti Ìran Yorùbá àti Ilẹ̀-Àjogúnbá wa; tí wọ́n sì ní Àṣà àti Ìṣe kan-náà, tí Ìtàn kan-náà sì pa wọ́n pọ̀; ní pàápàá, ní ti Ìran Yorùbá, tí ó jẹ́ pé kí òyìnbó-amúnisìn ó tó dé ni àgbáyé ti mọ̀ wá gẹ́gẹ́bí Ilẹ̀ Yorùbá; Ìjọba Yorùbá, Ilẹ̀-Àjogúnbá Yorùbá, àti Orílẹ̀-Èdè Yorùbá, tí a sì ti nṣe ìjọba-ara-ẹni láti ayé láíláí kí òyìnbó kankan ó tó wá sí orí ilẹ̀ wa láti wá ṣe ètò ìkónilẹ́rú àti Ìmúnisìn, gbẹ̀yìn-gbẹ̀yìn tí ó jẹ́ pé wọ́n ṣe Ètò ìkójọpọ̀ oríṣiríṣi àwọn orílẹ̀-èdè, tí wọ́n wá purọ́ pé orílẹ̀-èdè kanṣoṣo ni wọ́n, tí wọ́n wá pè wọ́n ní “Nàìjíríà,” ṣùgbọ́n tí ó jẹ́ Ètò Ìmúnisìn fún ànfààní Àwọn Amúnisìn Ìlú Gẹ̀ẹ́sì; tí Ìlú Gẹ̀ẹ́sì yí sì pàpà nṣe àtìlẹ́yìn fún, lẹ́yìn tí ọgọ́rún-ọdún Ètò Ìmúnisìn náà tilẹ̀ ti pé, tí ó tún ti lé, síbẹ̀ tí wọ́n ṣì nṣe Ètò Nàìjíríà ọ̀hún lọ, tí wọ́n tilẹ̀ wá tún nfipá jẹgàba lórí ilẹ̀ D.R.Y lẹ́yìn tí àwa D.R.Y ti kúrò nínú Ètò Amúnisìn Nàìjíríà náà, tí a tilẹ̀ ti padà di Orílẹ̀-Èdè-Aṣèjọba-Ara-Ẹni láti Ọjọ́ Kéjìlá, Oṣù Igbe, Ẹgbàá-Ọdún-Ó-Lé-Mẹ́rinlélógún.

Democratic republic of the Yoruba ominira new update | Yoruba Nation | Newest Nation in Africa, Youngest country in the World 2024

Ìbéèrè tí Màmá Ìran Yorùbá wá béèrè lọ́wọ́ àwọn òyìnbó-amúnisìn tí ó jẹ́ pé Ìran wọn, ti Ìlú Gẹ̀ẹ́sì ni ó ṣe Ètò Irọ́ tí wọ́n npè ní Nàìjíríà, ni pé, Kíni Ẹ̀tọ́ tí Ètò-Àtọwọ́dá tí wọ́n npè ní Nàìjíríà, kíni Ẹ̀tọ́ tí wọ́n ní láti jẹgàba sorí D.R.Y t’ó jẹ́ pé Orílẹ̀-Èdè ní Òtítọ́ àti ní Òdodo ni wá?

Lọ́nà míràn, ìbéèrè tí Màmá wa nbéèrè ni pé, Ìdí kíni ohun tí ó jẹ́ pé Ètò-Amúnisìn ni, èyíinì nì, Nàìjíríà, ìdí kíni ó fàá tí Ètò Àtọwọ́dá Ọmọ-Ènìyàn yí, fí máa-máa jẹgàba sorí ilẹ̀ Orílẹ̀-Èdè (ìyẹn D.R.Y).

Ẹ̀tọ́ wo ni Ètò lásán-làsàn, tí kìí ṣe orílẹ̀-èdè, ní, láti jẹgàba lé ilẹ̀ Orílẹ̀-Èdè Olómìnira?

Ìbéèrè nlá-nlà tí Màmá wa béèrè lọ́wọ́ àwọn Òyìnbó-Amúnisìn nìyí o! Lóbátán! Ìbéèrè yí ti ṢÍ AṢỌ LÓJÚ EÉGÚN WỌN! Ọ̀rọ̀ ti di wò-mí-nwò-ẹ́! Wọn ò rí ibi sá pamọ́ sí mọ́! Èyí tí ó túmọ̀ sí pé, gbogbo ẹ̀yin tí ẹ fi ipá dúró sórí ilẹ̀ D.R.Y, ìwọ Ayédatiwa, Ṣèyí Mákindé, Oyèbanjí, Adémọ́lá Adélékè, Jidé Sanwó-Olú, Dàpọ̀ Abíọ́dún; Abdulrahman Abdulrazaq, àti Ododo, aṣọ ti ṣí lójú eégún yín: kòròfo ni ẹ̀yin àti Nàìjíríà yín! Gbogbo àgbáyé ni ó ti mọ̀ báyi pé kò sí nkan tó njẹ́ Nàìjíríà ní ibikíbi ní àgbáyé! Kò sí orílẹ̀-èdè tó njẹ́ bẹ́ẹ̀!

Ẹ kúrò lórí ilẹ̀ D.R.Y !