Àṣírí ti tú o, kò sí ọjọ́ ọ̀la kankan mọ́ fún ìlú tí wọ́n ńpé ni Nàìjíríà èyítí ó f’ẹ̀gbẹ́ ti Orílẹ̀-Èdè wa, Democratic Republic of the Yorùbá, nítorípé àwọn aṣíwájú ati àwọn olóṣèlú wọn ti pawọ́pọ̀ ta gbogbo epo rọ̀bì wọn àti èyítí ó ṣì wà nínú ilẹ̀, wọn sì tí pín gbogbo owó náà láàrin ara wọn, ìdí rèé tí wọn kò fí lè rí epo rọ̀bì tà fún ilé ìfọpo Dangote. Abájọ tí wọ́n ńfi ojojúmọ́ jí rí ìyà ní ìlú yẹn.
Orílẹ̀-Èdè Yorùbá jẹ́ Orílẹ̀-Èdè Olómìnira ti ara rẹ̀. Gbogbo ìgbésẹ̀ tí orílẹ̀-èdè Nigerí àti àwọn gómìnà Nigeria, tí wọ́n ngbé l’orílẹ̀-èdè Yorùbá, gbogbo ẹ̀ pátápátá l’a nkójọ pọ̀ gẹ́gẹ́bí ẹ̀rí. pín sórí àgbàgbé ti X (Twitter)Àṣírí yìí tú jáde nínú ètò kan lórí ayélujára níbití wọ́n ti ńsọ̀rọ̀ nípa ìlú búburú náà. Wọ́n tún wípé lábẹ́ ìṣèjọba ààrẹ wọn àná, Munammadu Buhari ni alábàáṣiṣẹ́pọ̀ rẹ̀ kan, Mele Kyari ti ṣe pàsípààrọ̀ epo rọ̀bì náà pẹ̀lú ẹ̀yáwó bílíọ̀nù mẹ́ta dọ́là.
A mà dúpẹ́ lọ́wọ́ màmá wa Modúpẹ́ọlá Onitiri-Abiọla tí wọ́n gbà kí Olódùmarè lò wọ́n fún itusilẹ àwa ọmọ Yorùbá kúrò nínú oko ẹrú ìṣẹ́ àti ìyà àsopọ̀ pẹ̀lú Nàìjíríà, kíni àwa ọmọ aládé ìbá màa wí báyi.
Gbogbo àwọn èyí kò kàn wá ní Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá bíkòṣe ti ìjẹgàba wọn lóri ilẹ̀ wa lẹ́yìn tí a ti jáde kúrò nínú ìlú àwọn apanijayé Nàìjíríà láti ogúnjọ́ oṣù Bélú ẹgbẹ̀wá-ọdún-ó-lé-méjìlelogun tí a sì ti bẹ̀rẹ̀ ìjọba wa ní ọjọ́ Kejìlá oṣù Igbe ẹgbẹ̀wá-ọdún-ó-lé-mẹ́rìnlélógún tí a tí ṣe ìbúrawọlé fún olórí Adelé wa, baba wa Mobọlaji Ọlawale Akinọla Ọmọkọrẹ tí wọ́n sì ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ní pẹrẹu lọ́jọ́kan náà, okùn gbèsè Nàìjíríà sì tí bọ́ kúrò lọ́rùn tiwa.
Àkókò naa rèé fún gbogbo ọ̀dọ́ ilẹ̀ Yorùbá láti kọ́’gbọ́n. Ṣe irú àwọn àgbààgbà akótilétà ilẹ̀ Yorùbá yíì ṣeé tẹ̀lé bayii?
Àwọn tó ń darapọ̀ mọ́ àwọn àjèjì láti tá ohun àmúṣọrọ̀ tí ó jẹ́ ogún ibí gbogbo ọmọ Yorùbá àti pàápàá jùlọ, ọjọ́ ọ̀la àwọn ọ̀dọ́ wa, awon àgbààyà burúkú yìí wá ńfi owó náà tọ́jú àwọn ọmọ wọn, wọ́n sì ńṣe àkóbá fún àwọn ọ̀dọ́ tó kù, àwọn ìkà yí wá sọ ọ̀dọ́ Yorùbá di agbèrò, ọmọ ìta, aṣẹ́wó, olè, yahoo, ọmọ ẹgbẹ́ òkùnkùn, ọmọ l’ẹ́yìn olóṣèlú pẹlú àwọn tí ńgbé ènìyàn ṣòògùn owo àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ.
Wọ́n tún ńfi òògùn olóró ba ayé ọ̀dọ́ jẹ́ láti tún ayé àwọn ọmọ tiwọn ṣe. Óyẹ kí ọ̀dọ́ Yorùbá lè béèrè lọ́wọ́ àwọn ìkà wèrè àgbà yìí pé, ṣe wọ́n lè ṣètò ayé búburú báyìí fún àwọn ọmọ tiwọn náà? Nítorí náà, àsìkò rèé láti kúrò nínú ìgbèkùn ibí yìí.
A kí gbogbo ọ̀dọ́ Yorùbá kú oríire fún ọjọ́ ọ̀la tí ó dájú tí ó sì dára, nítorí pé màmá wa, Modúpẹ́ọlá Onitiri-Abiọla ni ètò tó dára tó sì rẹwà fún wọn gégébí àkọsílẹ ìlànà ètò ìṣèjọba tí màmá wa gbé kalẹ̀ fún wa.
Gbogbo ọ̀dọ́ Yorùbá níláti dìde báyìí láti fọwọsowọ́pọ̀ pẹ̀lú àwọn Adelé wá fún ìgbé ayé rere ati iṣelógo ọjọ́ ọ̀la wọn, nítorí ìyá wa ìrọ̀rùn ló bá dé tí sọ wípé gbogbo ọ̀dọ́ wa ní yóó rí ògo wọn lò ní Orílẹ̀-èdè D.R.Y pẹlú ìdánilójú.